1Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Ísírẹ́lì kò ní ọba.
2Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti lo oṣù mẹ́rin ní ilé baba rẹ̀
3ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀ tayọ̀ gbà á.
4Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.
5Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”
6Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó wọn láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”
7Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.
8Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.
9Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọlé.”
10Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jébúsì: ọ̀nà Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀.
11Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jébúsì tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jébúsì kí a sì sùn níbẹ̀.”
12Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, a ó ò dé Gíbíà.”
13Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gíbíà tàbí Rámà kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn.
14Wọ́n sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gíbíà tí ṣe ti àwọn Bẹ́ńjámínì.
15Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú náà láti wọ̀ ṣíbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.
16Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Éfúráímù, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gíbíà (ibẹ̀ ni àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko.
17Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìnàjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?”
18Ọmọ Léfì náà dá a lóhùn pé, “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbégbé tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Éfúráímù níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, èmi sì ń lọ sí ilé OLÚWA nísinsìn yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀.
19Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ-èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.”
20“Mo kí ọ kú ààbọ̀ sí ilé mi,” ni ìdáhùn ọkùnrin arúgbó náà. “Èmi yóò pèṣè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ìta.”
21Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹṣe wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.
22Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”
23Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹyin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.
24Kíyèsí i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúndíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwa òmùgọ̀ yìí sí.”
25Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Torí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́.
26Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀.
27Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsí i àlè rẹ̀ wà ní síṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu ọ̀nà ibẹ̀ mú,
28òun sì wí fún obìnrin náà pé, “Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀.
29Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ ó sì gé àlè rẹ̀ ní oríkeríke sí ọ̀nà méjìlá, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì.
30Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, “A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Ísírẹ́lì ti jáde tí Éjíbítì wá títí di òní olónìí. Ẹrò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn kí ẹ sọ fún wa ohun tí a ó ò ṣe!”