1Nígbà náà ni Dèbórà àti Bárákì ọmọ Ábínóámù kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:
2“Nítorí bí àwọn olórí ti ṣíwájú ní Ísírẹ́lì,nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,Ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA!
3“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ̀yin ìjòyè!Èmi yóò kọrin nípa OLÚWA, èmi yóò kọrinÈmi yóò kọrin sí OLÚWA: Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
3
4“OLÚWA nígbà tí o jáde lọ láti Ṣéírì,nígbà tí o yan láti ilẹ̀ Édómù,ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run ya,ìkúùkù àwọ̀sámọ̀ da omi wọn sílẹ̀.
5Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú OLÚWA Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì,níwájú OLÚWA ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
5
6“Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì,Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀;àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.
7Àwọn akọni ìletò dínkù,wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde,ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.
8Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì,ogun jíjà wọ ibodè ìlúa kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì
9Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lìàwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọẸ yín OLÚWA!
9
10“Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,Ní ọ̀nà jìnjìn sí
11ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo OLÚWA níbẹ̀,àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.
11“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn OLÚWA sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.
12‘Jí, jí, Dèbórà!Jí, jí, kó orin dìde!Dìde Bárákì!Kó àwọn ìgbékùn rẹ ní ìgbékùn ìwọ ọmọ Ábínóámù.’
12
13“Nígbà náà ni ó fi àwọn tókùjọba lórí àwọn ènìyàn;OLÚWA fún mi ìjọbalórí àwọn alágbára.
14Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì;Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá,láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.
15Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà;bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì,wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.Ní ipadò Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.
16Èéṣe tí ìwọ fi jókòó láàárin agbo àgùntànláti máa gbọ́ fèrè olùsọ́-àgùntàn?Ní ipadó Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.
17Gílíádì jókòó ní òkè odò Jọ́dánì.Èéṣe tí Dánì fi jókòó nínú ọkọ̀ ojú omi?Ásérì jòkòó ní etí bèbè òkun,ó sì n gbé èbúté rẹ̀.
18Àwọn ènìyàn Ṣébúlúnì fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Náfítalì ní ibi gíga pápá.
18
19“Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;àwọn ọba Kénánì jàní Tánákì ní etí odo Mégídò,ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.
20Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wáláti ibùjókòó wọn ni wọ́n ti bá Ṣísérà jà.
21Odò Kísónì agbá wọn lọ,odò àtijọ́ náà, odò Kíṣónì.Má a yan lọ ìwọ ọkàn mi, jẹ́ alágbára pẹ̀lú!
22Nígbà náà ni pátakò ẹṣẹ̀ ẹsin ki ilẹ̀,nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
23‘Ẹ fi Mérósì,’ bú ni ańgẹ́lì OLÚWA wí.‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò,nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ,láti dojúkọ àwọn alágbára.’
23
24“Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì,aya Hébérì ará Kénì,alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́.
25Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà;ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì.
26Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà.Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí,Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ.
27Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ó ṣubú; ó dúbúlẹ̀.Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wó lulẹ̀;ní ibi tí ó gbé wólẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú.
27
28“Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé,ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,‘Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn?’
29Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,
30‘Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù:ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà,ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,gbogbo wọn tí a kó ní ogun?’
30
31ⓐ “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé OLÚWA!Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn.nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”