Ìwé Onídájọ́ 8:1-35 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn àgbààgbà ẹ̀yà Éfúráímù sì bínú gidigidi sí Gídíónì wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Mídíánì jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀.

2Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fi wé tiyín? Àṣàkù àjàrà Éfúráímù kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Ábíésérì lọ bí?

3Ọlọ́run ti fi Órébù àti Ṣéébù àwọn olórí àwọn ará Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Móṣè ṣe tí ó tó fi wé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín.” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọ lẹ̀.

4Gídíónì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀ṣíwájú láti lépa àwọn ọ̀ta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jọ́dánì wọ́n sì kọjá sí òdì kejì.

5Ó wí fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ ogun mi ní oúnjẹ diẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Ṣébà àti Ṣálímúnà àwọn ọba Mídíánì.”

6Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Ṣúkótì fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Ṣébà àti Ṣálímúnà náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ?

7Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí OLÚWA bá fi Ṣébà àti Ṣálímúnà lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ìjù àti ẹ̀gún ọ̀gán ya ara yín.”

8Láti ibẹ̀, ó lọ sí Péníélì ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Súkótì ti dá a lóhùn.

9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Péníélì pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé èmi yóò wọ ilé ìṣọ́ yìí.”

10Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

11Gídíónì gba ọ̀nà tí àwọn dáràndáràn máa ń rìn ní apá ìhà ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbíà ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀.

12Ṣébà àti Ṣálímúnà, àwọn ọba Mídíánì méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gídíónì lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.

13Gídíónì ọmọ Jóásì gba ọ̀nà ìgòkè Hérésì padà sẹ́yìn láti ojú ogun.

14Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Ṣúkótì, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Ṣúkótì mẹ́tadínlọ́gọ́rin (77) fún un tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà ìlú náà.

15Nígbà náà ni Gídíónì wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ṣébà àti Sálímúnà nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Ṣébà àti Ṣálímúnà? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ”

16Ó mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Ṣúkótì lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n níyà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún aṣálẹ̀ àti ẹ̀gún ọ̀gàn.

17Ó wọ ilé ìṣọ́ Péníélì, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

18Gídíónì bi Ṣébà àti Ṣálímúnà pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tábórì, bá wo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.

19Gídíónì dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi OLÚWA búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò ní pa yín.”

20Ó yí padà sí Jétérì, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jétérì kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.

21Ṣébà àti Ṣálímúnà dá Gídíónì lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gídíónì bọ́ ṣíwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀sọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

22Àwọn ará Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.”

23Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jọba lórí yín. OLÚWA ni yóò jọba lórí yín.”

24Ó sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ọkàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Ísímáílì ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.)

25Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀.

26Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

27Gídíónì fi àwọn wúrà náà ṣe Éfódì èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Òfírà ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ ara wọn di aṣẹ́wó nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ fún Gídíónì àti ìdílé rẹ̀.

28Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Mídíánì ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbérí mọ́. Ní ọjọ́ Gídíónì, Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.

29Jerub-Báálì ọmọ Jóásìa padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.

30Àádọ́rin ọmọ ni ó bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.

31Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣékémù, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ábímélékì.

32Gídíónì ọmọ Jóásì kú ní ògbólógbó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin-ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ófírà ti àwọn ará Ábíésérì.

33Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gídíónì ni àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àgbérè tọ Báálì lẹ́yìn, wọ́n fi Báál-Beriti ṣe òrìṣà wọn.

34Wọn kò sì rántí OLÚWA Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn.

35Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jérú-Báálì (èyí ni Gídíónì) fún gbogbo ore tí ó ṣe fún wọn.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>