Ìwé Oníwàásù 10:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún ìpara ní òórùn burúkú, bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.

2Ọkàn ọlọgbọ́n a máa sí sí ohun tí ó tọ̀nà, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.

3Kó dà bí ó ti ṣe ń rìn láàrin ọ̀nà, òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n a sì máa fi han gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.

4Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ, ma ṣe fi àyè rẹ sílẹ̀; ìdákẹ́jẹ́jẹ́ le è tu àṣìṣe ńlá.

5Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.

6A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jù lọ, nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn àyè tí ó kéré jù lọ.

7Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ aládé ń fi ẹṣẹ̀ rìn bí ẹrú.

7

8Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán-an.

9Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe òkúta lẹ́jọ́ le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì-igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

9

10Bí àáké bá kú tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n yóò nílò agbára púpọ̀ ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.

10

11Bí ejò bá sán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

11

12Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.

13Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀; ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìṣínwín búburú.

14Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀

14kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ ta ni ó le è ṣọ fún-un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

15Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá lágbara kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìgboro.

15

16Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìranṣẹ́ rẹ̀ àti tí àwọn ọmọ aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.

17Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ, fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmọ̀tí para.

17

18Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, ilé a máa wú, bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.

18

19Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àṣè fún, wáìnì a máa mú ayé dùn, ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun—gbogbo.

19

20Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ, tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ìbùsùn rẹ, nítorí pé ẹyẹ ojú—ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>