Ìwé Oníwàásù 11:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Fún àkàrà rẹ ṣórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò ríi padà

2Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, nítorí ìwọ kò mọ ohun—ìparun tí ó le è wá ṣórí ilẹ̀

3Bí àwọ̀ṣánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ì hà Gúṣù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.

4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọ̀ṣańmọ̀ kò ní kórè.

4

5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ara tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun-gbogbo.

5

6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọ̀lẹ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákàn náà.

7Ìmọ́lẹ̀ dùn Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.

8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀ Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

8

9Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ. Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.

10Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>