Ìwé Oníwàásù 12:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tíì dé àti tí ọdún kò tíì ní ṣun mọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé, “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn”

2Kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, àti kí àwọ̀ṣánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

3Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba, nígbà tí àwọn tí ó ń lọ̀ dá kẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀, tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;

4Nígbà tí ilẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́; nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

5Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga àti ti ìfarapa ní ìgboro; nígbà tí igi álímọ́ǹdì yóò tanná àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ tí ìfẹ́ kò sì ní ru ṣókè mọ́ nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

6Rántí rẹ̀—kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́; kí ìṣa tó fọ́ níbi ìṣun, tàbí kí àyíká-kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà rí, tí ẹ̀mí yóò sì padà ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

7

8“Aṣán! Aṣán!” ni Oníwàásù wí. “Gbogbo rẹ̀ aṣán ni!”

9Kì í ṣe wí pé Oníwàásù jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.

10Oníwàásù wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

11Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí èso tí a kàn pọ̀ dáradára tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.

12Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ-ọ̀n mi, gba ìmọ̀ràn.

12Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.

13Níṣinsìn yìí, òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

14Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́ àti ohun ìkọ̀kọ̀, kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>