1Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá níṣinṣin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà já sí asán.
2“Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ire-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?”
3Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.
4
5Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.
6Mo gbé adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.
7
8Mo kó wúrà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbéríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin. Mo sì ní onírúurú àwọn obìnrin tí ọkan ọkùnrin le e fà sí.
9Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.
10
11
12
13
14
15
16
17Nítorí náà, mo kórìíra ìwà-láàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
18Mo kóòríra gbogbo ohun tí mo ti ṣíṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni.
19Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọgbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí òmùgọ̀? Ṣíbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.
20Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìṣimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn.
21Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.
22Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn?
23Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìṣinmi ní alẹ́. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú.
24
25Nítorí wí pé láìsí Ọlọ́run, ta ni ó le è jẹ tàbí ki o rí ìgbádùn?
26Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ni ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹlẹ́ṣẹ̀, o fún-un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun-ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí o tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, aṣán ni, ó dàbí ẹni a gbìyànjú àti mú.