Ìwé Oníwàásù 3:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Àsìkò wà fún ohun gbogbo àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.

2Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.

3Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú lára dá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.

4Ìgbà láti ṣunkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti sọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó

5Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn

6Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,

7Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀

8Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

9Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?

10Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.

11Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

12Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láàyè.

13Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.

14Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.

15Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀, ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀

16Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà ní bẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ní o wà ní bẹ̀.

17Mo rò nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́ Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀, Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò fún gbogbo ìṣe.”

18Mo tún ro pe “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fi hàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí.

19Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò ṣàn ju ẹranko lọ, nítorí pé aṣán ni yíyè jẹ́ fún wọn.

20Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí.

21Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ní?”

22Nígbà náà, ni mo wá ríi wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-in rẹ̀ kò sí!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>