1Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn: mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kòsì ní Olùtùnú kankan,agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lárawọn kò sì ní olùtùnú kankan.
2Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kútí wọ́n sì ti lọ,ó ṣàn fún wọn ju àwọntí wọ́n sì wà láàyè lọ.
3Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn juàwọn méjèèjì lọ:ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburútí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun.
4Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
5Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kòó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
6Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ pèlú wàhálà,àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
7Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:
8Ọkùnrin kan dá wà,kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbíwàhálà rẹ̀ kò lópin,ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé,“Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà”“àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”Eléyìí náà aṣán niiṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.
9Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan,nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn:
10Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè,ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubútí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!
11Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru.Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já
13Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,
14Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀.
15Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.
16Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.