Ìwé Oníwàásù 6:1-12 BYB2014 - Bible AI

1Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn.

2Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ohun ìní àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohun kóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfàní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Aṣán ni èyí, àrùn búburú gbáà ni.

3Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rún ọmọ kí ó sì wà láàyè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣíbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láàyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun-ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo ṣọ wí pé àbíkú ọmọ ṣàn jù ú lọ.

4Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ farapamọ́ sí.

5Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣinmi ju ti okùnrin náà lọ.

6Kó dà, bí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun-ìní rẹ̀. Kìí ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

7Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni ṣíbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí

8Kí ni àǹfàní tí ọlọgbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè? Kí ni èrè talákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tó kù?

9Ohun tí ojú rí sàn ju ìfẹnúwákiri lọ Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

9

10Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀; kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jùú lọ

11Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

12Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti aṣán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? kò sí!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>