Ìwé Oníwàásù 7:1-29 BYB2014 - Bible AI

1Orúkọ rere ṣàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ

2Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àṣè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn.

3Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ Ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le

4Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.

5Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

6Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú.

7Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

7

8Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.

9Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

9

10Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?” Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

10

11Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.

12Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá níi.

13Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe: “Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

14Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá ìkejì nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀.

15Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí: Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.

16Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?

17Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé

18Ó dára láti mú ọ̀kan kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀ Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

18

19Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára ju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú

19

20Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

20

21Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.

22Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.

23Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé, “Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n” ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.

24Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́, ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?

25Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀, láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwà búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

25

26Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27Oníwàásù wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí: “Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.

28Nígbà tí mo sì ń wá a kiri ṣùgbọ́n tí n kò rí ì mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrin ẹgbẹ̀rún ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin, kankan kí ó dúró láàrin gbogbo wọn.

29Eléyìí nìkan ni mo tíì rí: Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára, ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>