Ìwé Oníwàásù 8:1-17 BYB2014 - Bible AI

1Ta ni ó dàbí ọlọgbọ́n ènìyàn? Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo? Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

2Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

3Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró ní ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

4Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è ṣọ fún-un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọgbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

6Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

6

7Níwọ̀n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, tani ó le è sọ fún-un ohun tí ó ń bọ̀?

8Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbàá dúró nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀; bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

9Gbogbo ǹnkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń mú lò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kán wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tó kù fún ìpalára rẹ̀.

10Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú òsìkà—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

11Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi.

12Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òsìkà ènìyàn ń ṣe ọgọ́rùn-ún ibi ṣíbẹ̀ tí ó sì wà láàyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.

13Ṣíbẹ̀ nítorí tí òsìkà kò bẹ̀rù Ọlọ́run, kò ní dára fún wọn, ọjọ́ wọn kò sì ní gùn bí òjìji.

14Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òsìkà àti òsìkà tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo ṣọ wí pé eléyìí gan-an kò ní ìtumọ̀.

15Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnú yóò báa rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.

16Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé.

17Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láì bìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọgbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>