2Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
3Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde Abájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ.
4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá Ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
4
5Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Dúdú bí àgọ́ Kédárì Bí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì
6Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú Nítorí òòrùn mú mi dúdú Ọmọkùnrin ìyá mi bínú sími Ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà. Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú
7Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán. Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣán Ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
8Bí ìwọ kò bá mọ̀, Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ. Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.
9Olùfẹ́ mi, Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.
10Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀
11A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
12Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀. Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi. Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi.
14Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí mi Láti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì.
15Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
16Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura.
17Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárì Ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì.