Ìwé Orin Sólómónì 2:1-17 BYB2014 - Bible AI

1Èmi ni ìtànná Ṣárónì Bí ìtàná lílì àwọn àfonífojì

2Bí ìtànná lílì ní àárin ẹ̀gún ni olùfẹ́ mi ní àárin àwọn wúndíá.

3Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó, ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.

4Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè, Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi.

5Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èṣo ápù tù mi lára Nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

6Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra

7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú Kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè Kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú

7

8Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké

9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà

10Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olùfẹ́ mi, Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.

11Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá; Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

12Àwọn òdòdó fara hàn lórí ilẹ̀ Àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé A sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

13Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde Àwọn àjàrà nípa ìtànná wọn fún ni ní òórùn dídùn Dìde, wá, Olùfẹ́ mi; Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

14Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

15Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná.

16Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì.

17Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Bétérì.

le>