Ìwé Orin Sólómónì 3:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Ní orí ìbùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi Bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi

5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú

6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ìkuku èéfín tí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò?

7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Sólómónì, Àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, Àwọn akọni Ísírẹ́lì,

8Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

9Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; Ó fi igi Lébánónì ṣe é.

10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀ Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀ Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”

11Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì, kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé, Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e Ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

le>