Ìwé Orin Sólómónì 4:1-16 BYB2014 - Bible AI

1Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi! Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà. Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ Irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì.

2Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn.

3Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; Ẹnu rẹ̀ dùn. Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètì lábẹ́ ìbòjú rẹ

4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

5Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrin ìtànná lílì.

6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíá àti sí òkè kékeré tùràrí.

7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwa, olùfẹ́ mi; kò sì sí àbàwọ́n lára rẹ.

7

8Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì. Àwa wò láti orí òkè Ámánà, láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; Ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ,

10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

11Ètè rẹ ń kán dídùn afárá oyin, ìyàwó mi; wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ. Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lébánónì.

12Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábinrin mi, ìyàwó mi ìṣun tí a sé mọ́, oríṣun tí a fi èdìdì dì.

13Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pàmóńgánéètì ni ti òun ti àṣàyàn èso; kípírésì àti nádì,

14Nádì àti Ṣáfírónì, kálámúsì àti kínámónì, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjíá àti álóé pẹ̀lú irú wọn.

15Ìwọ ni ọgbà oríṣun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lẹ́bánónì wá.

16Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúṣù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde. Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

le>