1Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́
2Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”
3Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i
5Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn
6Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn
7Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
9Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ tí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀?
10Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.
11Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò
12Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́
13Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí ti ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjíá olóòórùn dídùn
14Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
15Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.
16Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátapáta. Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.