1Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a?
2Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ.
3Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì,
4Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà, Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù, ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5Yí ojú rẹ kúrò lára mi; nítorí ojú rẹ borí mi. Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì.
6Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì.
8Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúndíá láìníye.
9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ, ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún Àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un
10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
11Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pómégíránéètì ti rúdìí.
12Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàárin àwọn ènìyàn mi.
13Padà wá, padà wá, ìwọ Ṣúlámátì: padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣúlámátì wò, bí ẹni pé orin ijo Máhánáímù?