1Báwo ni ẹṣẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà, Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì àlìkámà tí a fi lílì yíká.
3Ọmú rẹ rí bí abo àgbọ̀nrín méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín-erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Héṣébónì ní ẹ̀bá ẹnu ìbodè Bátírábímù. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lẹ́bánónì tí ó kọ ojú sí Dámásíkù.
5Bí òkè kámẹlì ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́!
7Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà.
8Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ; Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú” Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, Àti èémi imú rẹ bí i ápù.
9Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ. Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀
9
10Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmí sì ni ẹni tí ó wù ú.
11Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò
12Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13Àwọn èṣo mánídárákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso ọ̀tún àti àkúgbó tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.