Ìwé Orin Sólómónì 8:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi sí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà.

2Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòrùn dídùn fún ọ mu àti oje èso pómégíránéètì mi.

3Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbá mí mọ́ra.

4Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà, Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè, Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

5Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti ihà, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀ ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

6Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí ìjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ iná OLÚWA.

7Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta.

8Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?

9Bí òun bá jẹ́ ògiri, Àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn, Àwa yóò fi pákó kédárì dí i

10Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

11Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónì ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún fàdákà.

12Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

13Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

14Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn.

le>