1Nítorí náà, ẹ fi àrankan gbogbo sílẹ̀ ni apákan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlára, àti sísọ ọ̀rọ̀ buburú gbogbo.
2Bí ọmọ ọwọ́ titun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yín lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà.
3
4
5Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kírísítì.
6
7
8
9
10
11Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àlejò àti èrò, láti fà sẹ́hìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun;
12Kí ìwà yín láàrin àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsí, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.
13Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa: ì bá à ṣe fún ọba, fún olórí.
14Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ìgbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere.
15Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn.
16Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ maṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
17Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba.
18Ẹ̀yin ọmọ-ọdọ, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.
19Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi oara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run.
20Ṣùgbọ́n ògo kínni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba sẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, èyí ní ìgbóríyìn-fún lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
21Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kírísítì pẹ̀lú jìyà fún-un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún-un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipaṣẹ̀ rẹ̀:
22
23Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.
24
25Nítorí tí ẹ̀yin ń ṣáko lọ bí àgùntàn, ṣùgbọ́n nísinsinyìí ẹ̀yin ti padà sí ọ̀dọ̀ olùsọ́-àgùntàn àti bíṣọ́ọ̀bù ọkàn yín.