1
2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì-sí.
3Nínù ìwà wòbìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀-òdì wọ̀nyìí yóò máa reẹ ẹ yín jẹ́ nípa ìtàn àsán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
4Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn ańgẹ́lì si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́.
5
6
7
8(nítorí ọkùnrin olóòótọ́ náà bí ó ti ń gbé àárin wọn, tí ó ń rí tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́)
9Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdẹwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn.
10Ṣùgbọ́n páàpáà àwọn tí ó ń tọ ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.
11Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ańgẹ́lì bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó ò ní wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa.
12Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ohun tí kò yé wọn. Wọ́n dàbí ẹranko tí a kò lè tù lójú, àwọn ẹ̀dá aláròse, tí a dá láti máa mú pa, bí ẹranko ni wọ́n yóò sí sègbé pẹ̀lú.
13Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jáyé nínú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àṣè pẹ̀lú yín.
14Ojú wọn kún fún panságà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀sẹ̀ dídá; wọ̀n ń tan àwọn tí kò dúró ṣinṣin; wọ́n yege nínú iṣẹ́ wọ̀bìà, ẹni ègún ni wọ́n.
15
16
17Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkuuku tí ẹ̀fúúfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé.
18Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìsìnà.
19Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọgá ènìyàn.
20Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olúgbála wá Jésù Kírísítì, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a buru jú ti ìṣáájú lọ.
21Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọ́n má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọ́n yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn.
22