1Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí;
2Kí ẹ̀yín lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì yín.
3Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn.
4Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.”
5
6Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé.
7Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsìnyìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.
8
9Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.
10Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná lúúlúú.
11Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà-mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run.
12
13
14Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀.
15Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un.
16Bí ó tí ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn ṣọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lọ́, bí wọ́n ti ń lo ìwé-mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.
17Nítorí náà ẹ́yín olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kiyé sára, kí a má baà fi ìsìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró-ṣinṣin yín.
18Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísítì; ẹni tí ògo wà fún nísinsìn yìí àti títí láé. Àmín.