Ìwé Rúùtù 2:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Náómì ní ìbátan kan láti ìdílé Elimélékì ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì.

2Rúùtù, ará Móábù sì wí fún Náómì pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojú rere rẹ̀ pàdé.” Náómì sì sọ fún-un pé, “Má a lọ, ọmọbìnrin mi.”

3Rúùtù sì jáde lọ láti ṣa ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Bóásì tí ó ti ìdílé Elimélékì wá ni ó lọ láé mọ̀ ọ́ mọ̀.

4Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí OLÚWA wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, “Kí OLÚWA bùkún fún ọ.”

5Bóásì sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”

6Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Móábù tí ó tẹ̀lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù ni.

7Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣa ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsìn yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”

8Nígbà náà ni Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣa ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin mi.

9Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”

10Rúùtù wólẹ̀, ó sì wí fún Bóásì pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsí mi, èmi àjèjì àti àlejò?”

11Bóásì sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàárin àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí tẹ́lẹ̀.

12Kí OLÚWA kí ó san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”

13Rúùtù sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ ṣíwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”

14Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan. Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.

15Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣa ọkà, Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàárin oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́.

16Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣa, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”

17Rúùtù sì ń ṣa ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lítà méjìlélógún).

18Ó sì gbé e lọ sí ìgboro, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí sà bi o tí pọ̀ tó, Rúùtù sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.

19Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣa ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.” Rúùtù sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì ni òun ti ṣiṣẹ́ lónìí.”

20Náómì sì wí fún-un pé, “Kí OLÚWA, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Náómì sì sọ ṣíwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tó láti ra ohun-ìní ìdílé padà.”

21Rúùtù, ará Móábù sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣa ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”

22Náómì sì sọ fún Rúùtù, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”

23Rúùtù sì bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin Bóásì ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà bálì àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>