Ìwé Rúùtù 4:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà náà ni Bóásì gòkè lọ sí ẹnu ìbodè ìlú, ó sì jòkòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó sún mọ́ Elimélékì jùlọ, arákùnrin tí Bóásì ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Bóásì pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jokòó.” Ó sì lọ jokòó.

2Bóásì sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbààgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí se bẹ́ẹ̀,

3ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Náómì tí ó dé láti ilẹ̀ Móábù fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin wa, Elimélékì.

4Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jòkòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà, rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.”

4Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”

5Nígbà náà ni, Bóásì sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Náómì àti lọ́wọ́ Rúùtù ará Móábù, ìwọ gbọdọ̀ fẹ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

6Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun-ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”

7ⓐ Ní ayé ìgbà a nì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàsípàrọ̀ ohun-ìní, fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnikejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Ísírẹ́lì fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.

8Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Bóásì wí pé, “Ìwọ rà á fúnràrẹ,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

9Nígbà náà ni Bóásì wí fún àwọn àgbààgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimélékì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Málíónì àti Kílíónì lọ́wọ́ Náómì.

10Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

11Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLÚWA jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rákélì àti Léà láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Éfúráta àti olókìkí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

12Kí OLÚWA fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Pérésì, ọmọkùnrin tí Támárì bí fún Júdà láti ipaṣẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”

13Báyìí ni Bóásì ṣe mú Rúùtù, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, OLÚWA sì mú kí ó lóyùn, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan.

14Àwọn obìnrin sì wí fún Náómì pé, “Ìyìn ni fún OLÚWA tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Ísírẹ́lì.

15Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16Náómì sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.

17Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì.

18Èyí ni ìran Pérésì: Pérésì ni baba Ésírónì,

19Ésírónì ni baba Rámú,

19Rámù ni baba Ámínádábù

20Ámínádábù ni baba Násónì,

20Násónì ni baba Sálímónì,

21Sálímónì ni baba Bóásì,

21Bóásì ni baba Óbédì,

22Óbédì ní baba Jésè,

22Jésè ni baba Dáfídì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>