Ìwé Sáàmù 1:1-6 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní pa ìmọ̀ràn àwọn ènìyàn búburú tàbí ti kò ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn pọ̀, tàbí ti kò si bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.

2Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú Rẹ̀ wà nínú òfin OLÚWA àti nínú òfin Rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

3Ó dàbí igi tí a gbìn sí eti odò tí ń ṣàn, tí ń so èso Rẹ̀ jáde ní àkókò Rẹ̀ tí ewé Rẹ̀ kì yóò Rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

3

4Kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

5Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

5

6Nítorí OLÚWA ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide