Ìwé Sáàmù 10:1-18 BYB2014 - Bible AI

1Èé ha ti ṣe, OLÚWA, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré? È ha ti ṣe tí ìwọ fi ara Rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

2Nínú àrékérekè ènìyàn búburú ti ó gbérò ni kí a ti mú wọn, lí a mú-un nínú ìlànà tí o gbérò.

3Ó ń fọ́nnu nínú ìfẹ́ inú ọkàn Rẹ̀; o bùkún olójúkòkòrò ó sì ń kẹ́gàn OLÚWA

4Ènìyàn búburú kò lè rí i nínú ìgbéraga Rẹ̀; kò sí àyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò Rẹ̀;

5Ọ̀nà Rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin Rẹ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀ta Rẹ̀.

6O wí fún ara Rẹ̀, “Kò si ohun tí ó le mì mí; Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo èmi kò si ní ní wàhálà.”

7ⓐ Ẹnu Rẹ̀ kún fún ẹ̀gàn àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wa lábẹ́ ahọ́n Rẹ̀.

8Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò; ó gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀, ojú Rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn talákà ní ìkọ̀kọ̀.

9O lúgọ ní bùba nínú pàǹtí; ó lúgọ ní bùba làti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n Rẹ̀.

10Àwọn ẹni ìpalára Rẹ̀ run, ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀; kí talákà bá a le bọ́ sí ọwọ́ agbára Rẹ̀.

11Ó wí fún ara Rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú Rẹ̀ mọ́ òun kì yóò rí i láéláé.”

11

12Dìde, OLÚWA! Gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

13Èeṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara Rẹ̀, “Kò ní pé mí láti ṣe ìṣirò”?

14Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ. talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

15Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pèé láti wa sírò fún iwà ìkà Rẹ̀ tí a kò le è rí.

15

16OLÚWA ń jọba láé àti láéláé; àwọn orílẹ̀ èdè yóò ti ilẹ̀ Rẹ̀ ṣègbé.

17Ìwọ́ gbọ, OLÚWA, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ ìgbe wọn,

18Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìni baba àti àwọn ti a ni lára, kí ọkùnrin, tí ó wà ní àyé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>