Ìwé Sáàmù 101:1-8 BYB2014 - Bible AI

1Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ OLÚWA, èmi yóò máa kọrin ìyìn.

2Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́sẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.

3Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí o yapa ni èmi kórìíra

3wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

4Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

4

5Ẹnikẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnikejì Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, oun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú Rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún.

5

6Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó le máa bá mi gbé; ẹni tí o bá ń rìn ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí.

7Ẹni tí o bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké ti yóò dúró ní iwájú mi.

7

8Ní ojojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà; èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>