2
3Nítorí tí ọjọ́ rú bí èéfin; egungun mi sì jóná bí ààrò
4Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
5Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.
6Èmi dà bí ẹyẹ igún ni ijù: èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7Èmi dìde; èmí dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8Ní ọjọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta ológosẹ́ mi ń gàn mí; àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi si da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omíjé.
10Nítorí ìbínú ríru Rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́ èmi sì rọ bí koríko
12Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, ni yóò dúró láéláé; ìrántí Rẹ láti ìran dé ìran.
13Ìwọ ó dìde ìwọ o sì ṣàánú fún Síónì, nítorí ìgbà àti ṣe ojú rere sí i; àkókò náà ti dé.
14Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ; wọ́n sì káànú ẹrùpẹ̀ Rẹ.
15Àwọn ayé yóò bẹ̀rù orúkọ OLÚWA, gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo Rẹ.
16Torí tí OLÚWA yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.
17Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní; kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
17
18Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin OLÚWA:
19“OLÚWA wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé,
20Láti gbọ́ ìrora ará túbú, lati tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21Kí a lè sọ orúkọ OLÚWA ni Síónì àti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.
22Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn OLÚWA.
22
23Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24Èmi sì wí pé; “Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25ⓐ Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.
26Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì.
27Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí ṣíbẹ̀, ọdún Rẹ kò sì ni òpin.
28Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò dúró ní iwájú Rẹ pẹ́; a o sì fi ẹsẹ̀ irú ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú Rẹ.”