1Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́.
2Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore Rẹ̀
3Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ jìn ọ́ tí ó sì wo gbogbo àrùn Rẹ̀ sàn,
4Ẹni tí o ra ẹ̀mí Rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí o fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5Ẹni tí o fi ohun dídara tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe Rẹ̀ le di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
5
6OLÚWA ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a nilára.
7Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;
8ⓐ OLÚWA ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé;
10Òun kì í ṣe sí wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san-án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedédé wa.
11Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.
12Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrun bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;
14Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;
16Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.
17ⓑ Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ OLÚWA ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ
18Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin Rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19OLÚWA ti pèsè ìtẹ́ Rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba Rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
19
20Yin OLÚWA, ẹ̀yin ańgẹ́lì Rẹ̀ tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́
21Yin OLÚWA, ẹ̀yin ogun ọ̀run Rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.
22Yin OLÚWA, gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ní ibi gbogbo ìjọba Rẹ̀.