1Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi. OLÚWA Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọlá ńláni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
2Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
3Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi-àjà ìyẹ̀wù Rẹ. Ìwọ ti ó ṣe àwọ̀sánmọ̀ ni kẹ̀kẹ́-ogun Rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí àpá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
4ⓐ Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ Rẹ, Ọ̀wọ́ iná ni àwọn olùránsẹ́ Rẹ.
5O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mi láéláé.
6Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
7Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí Rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá Rẹ ni wọ́n sálọ;
8Wọn ṣàn kọjá lórí àwọn òkè, wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
9Ìwọ gbé òpin tí wọn kò le kọjá Rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ní wọ́n kò ní lé bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.
9
10Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì; tí ó ń ṣàn láàrin àwọn òkè.
11Wọn fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òùngbẹ wọn.
12Àwọn ẹyẹ ojú òfurufu tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọn ń kọrin láàrin àwọn ẹ̀ka.
13Ó bú omi rìn àwọn òkè láti iyẹ̀wù Rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èṣo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.
14Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lò kí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà.
16Àwọn igi OLÚWA ni a bomi rin dáradára, Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.
17Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.
18Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó; àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.
18
19Òsúpá jẹ àmì fún àkókò òòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀.
20Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri.
21Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22Òòrùn ràn, wọn sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ìhò wọn.
23Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá Rẹ̀ títí di àṣálẹ́.
23
24Iṣẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó, OLÚWA! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá a Rẹ.
25Bẹ́ẹ̀ ni òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìṣàlẹ̀ láìníye ohun alàyè tí tóbi àti kékeré.
26Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Léfíàtanì, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú Rẹ̀.
26
27Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò Rẹ̀.
28Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó o jọ; nígbà tí ìwọ bá là ọwọ Rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29Nígbà tí ìwọ bá pa ojú Rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn o sì padà sí erùpẹ̀.
29
30Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí Rẹ, ní a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
31Jẹ́ kí ògo OLÚWA wà pẹ́ títí láé; kí inú OLÚWA kí ó dùn ní ti iṣẹ́ Rẹ̀
32Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
32
33Ní gbogbo ayé mí ní ń ó kọrin sí OLÚWA: èmi ó kọrin ìyìn sí OLÚWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.
34Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ ọ lọ́rùn bí mo tí ń yọ̀ nínú OLÚWA.
35Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́sẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́. Yin OLÚWA.
35Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi.