1ⓐ Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, ké pe orukọ Rẹ̀: Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;
2Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ gbogbo.
3Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀: Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá OLÚWA kí ó yọ̀.
4Wá OLÚWA àti ipá Rẹ̀; wa ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.
4
5Rantí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu Rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6Ẹ̀yin ìran Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jákọ́bù, àyànfẹ́ Rẹ̀.
7Òun ni OLÚWA Ọlọ́run wa: ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
7
8ⓑ Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó páláṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran;
9Májẹ̀mu tí ó ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù, àti ìbúra tí ó búra fún Ísáákì.
10Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé
11“Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánì gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún”.
12Nígbà tí wọn kéré níye, wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀
13Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè, láti ìjọba kan sí òmìrán.
14Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tí wọn:
15“Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi nibi.”
15
16Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà ó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run;
17Ó sì rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọn Jósẹ́fù tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18Wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ Rẹ̀ a gbé ọrùn Rẹ̀ sínú irin
19Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ́lẹ̀ fi ṣẹ títí ọ̀rọ̀ OLÚWA fi dá a láre.
20Ọba ránsẹ́ lọ tú u sílẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ Rẹ̀ aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbà Rẹ̀ ní ọgbọ́n.
22
23Ísírẹ́lì wá sí Éjíbítì; Jákọ́bù sì ṣe àtìpó ní ilé Ámù.
24OLÚWA, sì mú àwọn ọmọ Rẹ̀ bí síi ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ
25Ó yí wọn lọkàn padà láti korìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.
26Ó rán Mósè ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti Árónì tí ó ti yàn
27Wọn ń ṣé iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Ámù
28Ó rán òkùnkùn o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀?
29Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó pa ẹja wọn.
30Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá, èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣnṣin sì dìde, ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32Ó sọ òjò di yìnyín, àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn;
33Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn ó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn.
34Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé, àti kòkòrò ní àìníye,
35Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn, wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọ́n.
36
37Ó mú Ísírẹ́lì jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà Rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38Inú Éjíbítì dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Ísírẹ́lí ń bá wọ́n.
39Ó ta awọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ni ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40Wọn bèèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọ́n lọ́rùn.
41Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde; gẹ́gẹ́ bí odò tí ń ṣàn níbi gbígbẹ.
41
42Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ Rẹ̀ àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀.
43Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ Rẹ̀
44Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọn sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
45Kí wọn kí ó le máa pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó le kíyèsí òfin Rẹ̀.