1ⓐ Yin OLÚWA Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA, nítorí tí o ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí tí ó ṣeun; Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé.
2Ta ni ó le ròyìn iṣẹ́ agbára OLÚWA ta ni lè sọ nípa ìyìn Rẹ̀?
3Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí tí ń ṣe ohun tí ó tọ́
4Rántí mi, OLÚWA, Nígbà tí ó bá fi ojú rere Rẹ̀ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
5Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ìní Rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
5
6Àwa ti dẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe àwa ti ṣe ohun tí kò dá a a sì ti hùwà búburú
7Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Éjíbítì iṣẹ́ ìyanu Rẹ kò yé wọn wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Rẹ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní nibi òkun pupa
8Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ Rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá Rẹ di mímọ̀
9O bá òkun pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí ihà
10O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti ọwọ́ ọ̀tá ni ó ti gbà wọ́n
11Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12Nígbà náà wọn gba ìpínnú Rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn Rẹ.
13Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn Rẹ
14Nínú ihà ni wọn tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀ wọn dán Ọlọ́run wò
15Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
15
16Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mósè pẹ̀lú Árónì, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA.
17Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Dátanì mì ó bo ẹgbẹ́ Àbìrámù mọ́lẹ̀
18Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yin Rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú.
18
19Ní Hórébù wọ́n ṣe ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúù wọn sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara ìrìn.
20Wọn pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí í gbàwọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá fún Éjíbítì,
22Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ámù àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá òkun pupa
23Bẹ́ẹ̀ ní, ó sọ wí pé oun yóò pa wọ́n run bí kò ba ṣe tí Mósè, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú Rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́
24Nígbà náà, wọn kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ilérí Rẹ̀ gbọ́.
25Wọn ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́ràn sí OLÚWA.
26Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè sí wọn kí òun le jẹ́ kí wọn ṣubú nínú ihà,
27Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀ èdè láti fọ́nu wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
27
28Wọn dá ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Péórù, wọn sì ń jẹ ẹbọ ti a rú sí àwọn òkú òrìṣà
29Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-àrùn jáde láàrin wọn.
30Ṣùgbọ́n Fínéhásì dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán
31A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32Níbi omi Méríbà, wọn bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mósè nítorí wọn.
33Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mósè wá.
33
34Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí sọ fún wọn,
35Ṣùgbọ́n wọn dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn
36Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí o di ìkẹ́kùn fún wọn.
37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rúbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìsà.
38Wọn ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn. Wọn fi wọ́n rúbọ sí ère Kénánì, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀
39Wọn si fi ìṣe ara wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe panṣágà lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
39
40Nígbà náà OLÚWA bínú sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn Rẹ̀
41Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀ èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jọba lórí wọn.
42Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọ́n lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Ṣíbẹ̀ wọ́n si ń ṣọ̀tẹ̀ sí ì wọ́n sì sòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
43
44Ṣùgbọ́n o kíyèsí wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ Rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46Lójú gbogbo àwọn tí o kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú.
46
47ⓑ Gbà wá, OLÚWA Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrin àwọn aláìkọlà láti máa fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ Rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn Rẹ.
47
48Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láti ìrandíran Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”