Ìwé Sáàmù 107:1-43 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé.

2Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA kí ó wí bayí, àwọn ẹni tí ó ràpadà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

3Àwọn tí ó kó jọ láti ilẹ̀ wọ̀nnì láti ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn, láti àríwá àti òkun wá.

3

4Wọn ń rìn káàkiri ni ihà ni ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kòrí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé

5Ebi ń pa wọn, òùngbẹ gbẹ wọn, ó sì Rẹ̀ ọkàn wọn nínú wọn.

6Ní ìgbà náà wọn kígbe sókè sí OLÚWA nínú ìdàámú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn

7Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé

8Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

9Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa.

9

10Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin,

11Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo,

12Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13Ní ìgbà náà wọ́n ké pe OLÚWA nínú ìdàámú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún OLÚWA Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.

16

17Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn

18Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ikú.

19Nígbà náà wọn kígbe sí OLÚWA nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdàámú wọn

20Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ara wọn sí dá ó sì yọ̀ wọ́n nínú isà òkú.

21Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

22Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ̀.

23Àwọn ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọn jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.

24Wọn ri iṣẹ́ OLÚWA, àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ nínú ibú

25Nítorí tí ó pasẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru Rẹ̀ sókè.

26Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọn sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú ọkan wọn di omi

27Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin.

28Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí OLÚWA nínú ìdàámú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.

29Ó sọ ìjì di ìdákẹ́-rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ní rirú omi Rẹ̀ duro jẹ́ẹ́;

30Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,

31Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

32Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárin àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yín ín ní ìjọ àwọn àgbà.

32

33Ó sọ odò di ihà, àti orisun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

34Ilẹ̀ eleso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú Rẹ̀;

35O sọ ihà di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di oríṣun omi

36Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pìlẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé

37Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò ma so èso tí ó dára;

38Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dín kù.

38

39Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù

40Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí

41Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bi agbo ẹran

42Àwọn tí ó dúró sì ríi, inú wọn sì dùn ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu Rẹ̀ mọ́.

42

43Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsí nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>