1ⓐ Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi o máa fi ọkàn mi kọrin
2Jí ohun èlò orin àti háápù èmi ó jí ní kùtùkùtù
3Èmi ó yìn ọ, Ọlọ́run nínú àwọn orílẹ̀ èdè èmi o kọrin Rẹ nínú àwọn ènìyàn
4Nítorí tí o tóbi ní àánú Rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo Rẹ dé àwọ̀sánmọ̀
5Gbé ara Rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo Rẹ lórí gbogbo ayé.
5
6ⓑ Gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún Rẹ, se igbala, ki o si da mi lóhùn
7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ níbi mímọ́ “Ní ìsẹ́gun ní èmi ó ké Sékémù èmi yóò sì wọ́n ibi gíga Sukobù
8Gílíádì ni tèmi, Mánásè ni tèmi Éfuraimù ní ìbòrí mi Júdà ní olófin mi
9Móábù si ni ìkòkò ìwàsẹ̀ mi lórí Édómù ní èmi ó bọ́ bàtà mi sí lórí òkè Fílísitínì ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
9
10Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi Ta ni yóò sìn mi wá sí Édómù
11Ìwọ Ọlọ́run há kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
12Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni
13Nípaṣẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí oun ó tẹ àwọn ọ̀ta wa mọ́lẹ̀.