1Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún Má ṣe dákẹ́
2Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
3Wọn fi ọ̀rọ̀ ìrira yí mi káàkiri; wọ́n bá mi ja láìnídìí
4Nípo ifẹ̀ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi, ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
5Wọ́n sì fi ibi san ire fún mi àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
5
6Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojú kọ ọ́ jẹ́ kí àwọn olufisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.
7Kí a dá a lẹbi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà Rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
8ⓐ Kí ọjọ́ Rẹ̀ kí ó kúrú kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ Rẹ̀
9Kí àwọn ọmọ Rẹ̀ di aláìní baba kí aya Rẹ̀ sì di opó
10Jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ ounjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àléjò kí o kó èrè isẹ́ Rẹ̀ lọ
12Má ṣe jẹ́ kí ẹnikan ṣe àánú fún un tàbí kí wọn káàánú lórí àwọn ọmọ Rẹ̀ aláìní baba
13Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ Rẹ̀ kúrò kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba Rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ OLÚWA Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú OLÚWA kí o le ge ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
15
16Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíní sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí Rẹ̀: bi inú Rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ́ẹ̀ ni ki ó jìnnà sí ì.
18Bí ó ti fi ègún wọ ará Rẹ̀ lásọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá si inú Rẹ̀ bí omi
19Jẹ́ kí o rí fún un bí aṣọ tí a dàbòó ní ara, àti fún àmùrè ti ó fi gbàjá nígbà gbogbo
20Èyí ni èrè àwọn ọ̀ta mi làti ọwọ́ OLÚWA wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀kàn mi.
20
21Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi OLÚWA, ṣe rere fún mi nítorí orúkọ Rẹ Nítorí ti àánú Rẹ dara, ìwọ gbà mí
22Nítorí pé talákà àti aláìní ni mí, àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23Èmi ń kọja lọ bí òjiji tí óńfà sẹ́yìn, mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24Eékún mi di aláìlera nítorí ààwẹ̀ gbígbà ẹran ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25ⓑ Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi; nígbà tí wọn wò mí, wọn gbọn orí wọn.
25
26Ràn mí lọ́wọ́, OLÚWA Ọlọ́run mi; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ.
27Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ Rẹ ni èyí wí pé ìwọ, OLÚWA, ni o ṣe é.
28Wọ́n o máa gégùn-ún, ṣùgbọ́n ìwọ má súré; Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ yóò yọ̀
29Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú kí á sì fi ìdàrú dàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
29
30Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yìn OLÚWA gidigidi ní àárin ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín
31Nítorí ó dúró ni apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn Rẹ̀ lẹ́bi.