1Ìgbẹ́kẹ̀lé mí wà nínú OLÚWA. Báwo ní ẹ̀yin o ṣe sọ fún ọkàn mi pé: “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè Rẹ.
2Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà Rẹ̀; wọn ti ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìjì sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
3Nígbà tí ìpìlẹ̀ ba bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?”
3
4OLÚWA ń bẹ nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀; OLÚWA ń bẹ lórí ìtẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú Rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5OLÚWA ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ ìwà ipá ni ọkàn Rẹ̀ kórìíra.
6Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti ìmí ọjọ́ tí ń jó; àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
6
7Nítorí olódodo ní OLÚWA, o fẹ́ràn òdodo; ẹni ìdúróṣinṣin yóò sì rí i.