Ìwé Sáàmù 110:1-7 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ  OLÚWA sọ fún OLÚWA mi, pé ìwọ jòkòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ di àpótí ìtisẹ̀ Rẹ

2OLÚWA yóò na ọ̀pá agbára Rẹ̀ láti Síónì wá, ìwọ jọba láàrin àwọn ọ̀tá Rẹ.

3Àwọn ènìyàn Rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun Rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà Rẹ.

4ⓑ  OLÚWA ti búra, kò sí ní yí ọkàn padà pé, ìwọ ní àlúfà títí láé, titẹ̀ àpẹẹrẹ Melekisédékì.

4

5OLÚWA ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú Rẹ̀

6Yóò ṣe ìdájọ́ láàrin kènfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara; yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

7Yóò mú nínú òdò ṣíṣàn ní ọ̀nà: nítorí náà ni yóò ṣe gbe orí sókè.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>