Ìwé Sáàmù 111:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ máa yin OLÚWA. Èmi yóò máa yìn OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwujọ àwọn olóòtọ́, àti ní ijọ ènìyàn.

2Iṣẹ́ OLÚWA tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀.

3Iṣẹ́ Rẹ̀ ní ọlá ńlá àti ògo: àti òdodo Rẹ̀ dúró láéláé.

4Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, láti máa rántí: OLÚWA ni olóore ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.

5O ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀: oun ń rántí májẹ̀mú Rẹ̀.

6Ó ti fi hàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ agbára isẹ́ Rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀lérí ni ìní

7Iṣẹ́ ọwọ Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin Rẹ̀ sì dájú.

8Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ní a ṣe wọ́n.

9Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn Rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú Rẹ̀ títí láé: mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ní orúkọ Rẹ̀.

9

10Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin Rẹ̀: ìyìn Rẹ̀ dúró láé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>