Ìwé Sáàmù 112:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA. Ìbùkún ni fún Ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó ní inúdídùn ńlá sí àwọn òfin Rẹ̀.

2Iru ọmọ Rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòótọ́ ni a ó bùkún fún

3Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé Rẹ̀: òdodo Rẹ̀ sì dúró láé.

4Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ni òkùnkùn: olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.

5Ọkùnrin rere fí ojú rere hàn, a sì wín ni, ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ Rẹ̀.

6Dájúdájú kì yóò le yí ni ìpo padà láéláé: olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí ní ayérayé.

7Òun kì yóò bèèrè ìyìn búburú: ọkàn Rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLÚWA.

8Ó ti mú ọkàn Rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bàá, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkan Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀.

9ⓐ Ó ti pin ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú; Nítorí òdodo Rẹ̀ dúró láé; ìwọ Rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

9

10Ènìyàn búburú yóò rí, inú wọn yóò sì bàjẹ́, yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù: èròngbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>