1Ẹ máa yin OLÚWA, yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLÚWA, ẹ yin orúkọ OLÚWA.
2Fi ìbùkún fún orúkọ OLÚWA láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3Láti ìlà òòrun títí dé ìwọ Rẹ̀ orúkọ OLÚWA ni kí á máa yìn.
3
4OLÚWA ga lórí gbogbo ayé, àti ògo Rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5Ta ló dàbí OLÚWA Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga.
6Tí ó Rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
6
7Ó gbé òtòsì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
8Kí ó le mú-un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé àwọn ènìyàn Rẹ̀.
9Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ Rẹ̀.