1Kí ṣe fún wa, OLÚWA kì ṣe fún wá, ṣùgbọ́n fún orúkọ Rẹ̀ ní a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ Rẹ.
2Torí kí ní àwọn aláìkọlà yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà.
3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
4ⓐ Òrìṣà fàdákà àti wúrà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn
5Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
6Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ràn: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọ́n kò fi gbóòórùn
7Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
8Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.
11
12OLÚWA tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Ísírẹ́lì; yóò bùkún ilé Árónì.
13ⓑ Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLÚWA, àti kékeré àti ńlá.
14OLÚWA yóò mú ọ pọ̀ síi síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ Rẹ̀.
15Ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.