Ìwé Sáàmù 119:1-176 BYB2014 - Bible AI

1Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́sẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLÚWA,

2Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin Rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

3Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀.

4Ìwọ ti la ìlànà Rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

5Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin Rẹ̀ mọ́!

6Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsí àṣẹ Rẹ̀ gbogbo.

7Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo Rẹ̀.

8Èmi yóò gbọ́ràn sí asẹ Rẹ̀: Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátapáta.

8

9Báwo ni àwọn èwe ènìyàn yóò ti ṣe pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

10Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yàpa kúrò nínú àṣẹ̀ Rẹ.

11Èmi ti pa ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ

12Ìyìn ni fún OLÚWA; kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

13Pẹ̀lú ètè mi èmi tún sírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu Rẹ.

14Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹ bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá.

15Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹ èmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ

16Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ.

17Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

18La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ.

19Àlejò ní èmi jẹ́ láyé; Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi.

20Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.

21Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-ún tí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ.

22Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́.

23Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.

24Òfin Rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.

25Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀; pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ.

26Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

27Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

28Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

29Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ.

30Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin Rẹ.

31Èmi yára di òfin Rẹ mú. OLÚWA má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

32Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

33kọ́ mi, OLÚWA, láti tẹ̀lé àṣẹ Rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsíi pẹ̀lú ọkàn mi.

35Fi ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ hàn mí, nítorí nínú Rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

36Yí ọkàn mi padà sí òfin Rẹ̀ kí ó má ṣe sí ojú kòkòrò mọ́.

37Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ayé mí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

38Mú ìlérí Rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí òfin Rẹ dára.

39Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù ni torí tí idájọ́ Rẹ dára.

40Kíyèsíi ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ Rẹ! Pa ayé mí mọ́ nínú òdodo Rẹ.

41Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLÚWA, ìgbàlà Rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ;

42Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ.

43Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ Rẹ

44Èmi yóò máa gbọ́ràn sí òfin Rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.

45Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jáde.

46Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin Rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,

47Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ Rẹ nítórí èmi ni ìfẹ́ wọn.

48Èmi gbé ọwọ̀ mi sókè nítorí àṣẹ Rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àsàrò òfin Rẹ̀.

49Rántí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.

50Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinu Rẹ pa ayé mi mọ́.

51Àwọn agbéraga fi mi ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin Rẹ.

52Èmi rántí àwọn òfin Rẹ ìgbàanì, OLÚWA, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.

53Ìbínú dìmí mú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú tí wọ́n ti kọ òfin Rẹ sílẹ̀.

54Òfin Rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.

55Ní òru èmi rántí orúkọ Rẹ, OLÚWA, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́

56nitori ti mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ gbọ́.

57Ìwọ ni ìpín mi, OLÚWA: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

58Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

59Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ.

60Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ.

61Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

62Ní àárin ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo Rẹ̀.

63Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

64Ayé kún fún ìfẹ́ Rẹ OLÚWA Kọ́ mi ní òfin Rẹ.

65Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, OLÚWA.

66Kọ́ mi ni ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ Rẹ.

67Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti sìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsinyí èmi gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

68Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà Rẹ.

69Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti Rẹ̀ mí pẹ̀lú èké èmi pa ẹ̀kọ́ Rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

70Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin Rẹ.

71Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin Rẹ.

72Òfin tí ó jáde láti ẹnu Rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ

73Ọwọ́ Rẹ ní ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ Rẹ.

74Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

75Èmi mọ̀, OLÚWA, nítorí òfin Rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

76Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ.

77Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi.

78Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pamí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

79Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ yí padà sí mí, àwọn tí ó ní òye òfin Rẹ.

80Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin Rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

81Ọkàn mi ń fojú sọ́nà nítorí ìgbàlà Rẹ, ṣùgbọ́n èmi tí mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

82Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wí wo ìpinu Rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”

83Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí àmọ́ wáìnì nínú èéfín, èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

84Báwo ni ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?

85Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin Rẹ.

86Gbogbo àsẹ Rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé: rànmílọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láì nídìí.

87Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ̀ ẹ̀kọ́ Rẹ.

88Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu Rẹ̀ gbọ́.

89Ọ̀rọ̀ Rẹ, OLÚWA, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run

90Òtítọ́ Rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.

91Òfin Rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.

92Bí òfin Rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.

93Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́

94Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ Rẹ.

95Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsí ẹ̀rí Rẹ.

96Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ Rẹ aláìlópin ni.

97Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin Rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

98Àṣẹ Rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀ta mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.

99Èmi ní iyè ińu ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin Rẹ.

100Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ.

101Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ Rẹ.

102Èmi kò yà kúrò nínú òfin Rẹ, nítorí ìwọ fún rarẹ̀ ni ó kọ́ mi.

103Báwo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!

104Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ Rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

105Ọ̀rọ̀ Rẹ ni ó ṣe fítílà sí ẹṣẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi

106Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo Rẹ.

107A pọ́n mi lójú gidigidi; OLÚWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ

108OLÚWA, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin Rẹ̀.

109Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

110Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò sìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ.

111Òfin Rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.

112Ọkàn mi ti lé pípa òfin Rẹ mọ́ láé dé òpin.

113Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.

114Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

115Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!

116Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

117Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ.

118Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

119Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.

120Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ

121Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

123Ojú mi kùnà, fún wí wo ìgbàlà Rẹ, fún wíwo ìpinu òdodo Rẹ.

124Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

125Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin Rẹ

126Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, OLÚWA; nítorí òfin Rẹ ti fọ́.

127Nítorí èmi fẹ́ràn àsẹ Rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

128Nítorí èmi kíyèsí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ Rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

129Òfin Rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè.

131Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ.

132Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ.

133Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

134Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ.

135Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

136Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137Olódodo ni ìwọ OLÚWA ìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin

138Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139Ìtara mi ti pami run, nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá.

140Wọ́n ti dán ìpinnu Rẹ wò pátapáta ìránṣẹ́ Rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

141Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ.

142Òdodo Rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin Rẹ̀.

143Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àsẹ Rẹ ni inú dídùn mi,

144Òfin Rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òyé kí èmi lè yè.

145èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dámi lóhùn OLÚWA, èmi yóò sì gbọ́ràn sí àsẹ Rẹ.

146Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́.

147Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìràn lọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

148Ojú mi ṣááju ìsọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ r.

149Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ: pa ayé mí mọ́, OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

150Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin Rẹ.

151Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, OLÚWA, àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́.

152Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

153Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

154Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, OLÚWA; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

159Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ; pa ayé mi mọ́, OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ; gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

161Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

162Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ.

164Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo Rẹ.

165Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin Rẹ, kò sì si ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166Èmi yóò dúró de ìgbàlà Rẹ, OLÚWA, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ Rẹ.

167Èmi gba òfin Rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀ púpọ̀

168Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ Rẹ àti òfin Rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

169Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú Rẹ, OLÚWA; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

170Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú Rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

171Ètè mi yóò sọ ìyin jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ.

172Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ Rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ Rẹ jẹ́ òdodo.

173Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ ṣetan láti rànmílọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ Rẹ.

174Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà Rẹ, OLÚWA, àti òfin Rẹ jẹ́ dídùn inú mi.

175Jẹ́ kí èmi wà láàyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin Rẹ mú mi dúró.

176Èmí ti sìnà bí àgùntàn tí ó sọnùú wá ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ Rẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>