1Ràn wá lọ́wọ́, OLÚWA nítorí ẹni ìwà bí Ọlọ́run kò sí mọ́;Olótìítọ́ tí pòórá kúrò láàrin àwọn ènìyàn.
2Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
2
3Kí OLÚWA kí ó gé ètè èké wọnàti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
4tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;àwa ní ètè wa: ta ni ọ̀gá wa?”
4
5“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbáraàti ìkéróra àwọn aláìní,Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni OLÚWA wí.“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn”
6Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì jẹ aláìlábùkù,gẹ́gẹ́ bí fàdákà ti a yọ́ nínú ìléru àmọ́,tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.
6
7OLÚWA, ìwọ yóò pa wá mọ́kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
8Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kirinígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òṣì láàrin àwọn ènìyàn.