1Èmi ké pe OLÚWA nínú ìpọ́njú mi, ó sì dámi lóhùn
2Gbà mí, OLÚWA, kúrò lọ́wọ́ ète èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kín kí a tún ṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4Òun yóò bá ọ́ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú eyin iná igi ìgbálẹ̀.
4
5Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Mésékì, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kédárì!
6Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrin àwọn tí ó kóríra àlàáfíà.
7Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni ti wọn.