Ìwé Sáàmù 121:1-8 BYB2014 - Bible AI

1Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá

2Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ OLÚWA wá Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé

3Òun kì yóò jẹ́ kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

4Kíyèsí, ẹni tí ń pa Ísírẹ́lì mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

5OLÚWA ni olùpamọ́ Rẹ; OLÚWA ní òjìji Rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ

6Oòrùn kì yóò pa ọ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

6

7OLÚWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn Rẹ mọ́

8OLÚWA yóò pa àlọ àti ààbọ̀ Rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>