1Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé Ẹ jẹ́ kí a lọ sílé OLÚWA.
2Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè Rẹ, ìwọ Jérúsálẹ́mù.
2
3Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà OLÚWA, ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ OLÚWA.
5Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.
5
6Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù; àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀, àti ire nínú ààfin Rẹ̀.
8Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsìyí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀;
9Nítorí ilé OLÚWA Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ire Rẹ̀.