1“Ìba má ṣe pé OLÚWA tí ó ti wà fún wa” ni kí Ísírẹ́lì kí ó máa wí nísinsìn yìí;
2“Ìbá má ṣe pé OLÚWA tó wà ní tiwa,” Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
3Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láàyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wá
4Nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
5Nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.