1Nígbà tí OLÚWA mú ìkòlọ Síónì padà, àwa dàbí ẹni tí o ń lá àlá.
2Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn aláìkọlà pé, OLÚWA ṣe ohun ńlá fún wọn.
3OLÚWA ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀.
3
4OLÚWA mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúsù.
5Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.
6Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí Rẹ̀.