Ìwé Sáàmù 127:1-5 BYB2014 - Bible AI1Bí kò ṣè pé OLÚWA bá kọ́ ile náà àwọn tí n kọ ọ ńṣiṣẹ́ lásán ni; bí kò sé pé OLÚWA bá pa ilú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.2Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù lati pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ́ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ire fún olùfẹ́ Rẹ̀ lójú ọ̀run. 23Kíyèsí i, àwọn ọmọ ni ìní OLÚWA: ọmọ inú sì ni èrè Rẹ̀.4Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe5Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ààbò Rẹ̀ kún fún wọn; ojú kì yóò tì wọ́n, ṣùgbọ́n wọn yóò sẹ́gun àwọn ọ̀ta ní ẹnu ọ̀nà.